Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ, Shettima Rọ Àwọn Akẹ́ẹ̀kọ́jáde Láti Lo Ẹ̀bùn Wọn

190

 

Igbákejì ààrẹ Kashim Shettima ti rọ àwọn akẹ́ẹ̀kọ́jáde tuntun lati lo ẹbùn tí Ọlọ́run fún wọn ki wọn sì tún sa ipa tiwọn láti tún orílẹ̀-èdè yi kọ́, kí wọ́n máṣe máa fẹsẹ̀ gbálẹ̀ káàkiri pé àwọn n wa iṣẹ́ káàkiri sùgbọ́n ki won jẹ́ kí Nàìjíríà ni ọjọ́ ọ̀la tó dára.

Ó sọ èyí nígbà ti olórí àwọn òṣìṣẹ́ fún ààrẹ tó tún jẹ́ agbẹnuso ilé ìgbìmọ̀ asojú sòfin, Femi Gbajabiamila ṣáájú àwọn akẹ́kọ́-yege ti second cohort of the Legislative Mentorship Initiative lọ se àbẹ̀wò sí Ilé igbákejì ààrẹ ní Abúja ni ọjọ́ Ọjọ́rú.

Igbakeji aare Kashim Shettima gboriyin fún àwọn akẹkọ-yege fún ìmọ ijinle Kọmputa wọn tó danto, o wa so fún wọn pé ọ ṣe pàtàkì láti jẹ kori wọn ya sí idagbasoke orile-ede yìí.

Àwọn àwòrán tó kù:

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Comments are closed.

button