Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje CAFCC: Ikọ̀ Club African Fi Ẹ̀yìn Ikọ̀ Rivers United Gbolẹ̀ Ní Tunisia

201

Wọ́n lu iko Rivers United FC ti orílẹ̀-èdè yìí ni àlùbolẹ̀ láti ọwọ́ ikọ̀ Tunisia’s Club Africain pẹ̀lú ayò mẹ́ta sí òdo ni ibi ìdíje CAF Confederation Cup ìpín C, ni orí pápá Stade de Rades, ìlú Tunis, orílẹ̀-èdè Tunisia.

Agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà se bẹbẹ fún ikọ̀

Club Africain lẹ́yìn tó gbá ayò méjì wọlé fún wọn ní isẹ́ju mẹ́fà àti márùn lélógójì abala àkọ́kọ́.Kingsley Eduwo yọ̀ pẹ̀lú akẹgbẹ rẹ̀ fún oríire yìí. Rami Bedoui tún fi ọba le ni isẹjlẹ́ú mọ́kàndínláàdọ̀rin

O wá túmọ̀ sì pé ikọ̀ Rivers United ti ja si ipò kẹta nínú ipin C, lẹ́yìn Àmì mẹ́fà nínú ìdíje mẹ̀rin.

Club Africain wà lókè ténté pẹ̀lú àmì ayò mẹ́sàn -án pẹlu ifọ̀kanbalẹ̀

Níínú ìdíje ìpín C miran, Dreams FC  ti Ghana borí pẹlú ayò mẹ̀rin sí òdo (4-0 ) nígbà tí wọn wọ̀yá ija pelu APC Lobito lati Angola, wọn sì ni àmì mẹ́sàn án bákannáà, wọ́n wá ní ipò Kejì lórí tábìlì

Rivers United  ni lati bori ifagagbaga pẹ̀lú ikọ̀ Dream FC ati APC Lobito  kí àlá àti tẹ̀ síwájú ìdíje CAF Confederation Cup le wá sí ìmúsẹ.

Àbájáde eré bọọlu ti CAF Confederation Cup, ọjọ kẹrin níyì:

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button