Àjọ Panápaná ẹ̀ka ti Ìlú Èkó mú ìgbéga bá Ẹgbẹ̀rún Méjì Ó Dín Díẹ(1,695) àwọn Òṣìṣẹ́ rẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìgbéga àti ìdánilọ́lá náà, igbákejì ọ̀gá àgbà ẹ̀ka àjọ náà, Chika Njoku sọ pé àfojúsùn wọn dá lórí dídóòlà ẹ̀mí àti dukia àwọn ènìyàn.

Ọ̀gá àgbà náà wa rọ àwọn òṣìṣẹ́ to ní ìgbéga náà láti túbọ̀ tẹra mọ iṣẹ́ wọn.

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ tó ní igbega sọ wipe, èyí fún òun àti àwọn akẹgbẹ́ òun ní ìwúrí lati túbọ̀ múra dáradára sí iṣẹ wọn. Ó dupe lọ́wọ́ àwọn tó se ètò náà tí wọ́n kàwọ́n yẹ.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san