Take a fresh look at your lifestyle.

Denmark, Amẹ́ríkà fẹnukò lórí àdéhùn ààbò

Eyitayó Fauziat Oyetunji

183

Denmark ti fẹnukò lórí àdéhùn ààbò pẹ̀lú Amẹ́ríkà léyìí tí yóò mú kí ológun Amẹ́ríkà àti àwọn ohun ìjà ogun wọn wà ní Danish, Adarí orílẹ̀-èdè náà Mette Frederiksen ló sọ èyí.

Wọn ṣe ikede adehun ọlọdun mẹwaa yii lẹyin ti Amerika buwọlu iru adehun yii pẹlu Finland ati Sweden ni oṣu yii.

Eyi tumọ si pe awọn ọmọ ogun Amẹrika ati awọn ohnu ija wọn le wa ni orilẹ-ede Denmark,” Frederiksen sọ eyi fun awọn oniroyin ni bi apejọ awọn akọroyin.

Adehun naa, ti Denmark ati Amẹrika bẹrẹ iduna dura rẹ ni osu keji ọdun to kọja, yoo gba ibuwọlu laipẹ ninu ọsẹ yii ti yoo si di dandan nigba ti wọn ba ti gba isofin ti nilo wọle ni bi ọdun kan si asiko ti a wa yii, Frederiksen sọ bayii.

Ni ọjọ Aje Finland buwọlu Adehun ifọwọsowọpọ aabo pẹlu Amẹrika lati jẹ ki awọn ọmọ ogun Amẹrika ni anfaani to kun jakejado orilẹ-ede Nordic si agbegbe aala to gun pẹlu Russia.

 

Comments are closed.

button