Take a fresh look at your lifestyle.

Dan-dan Ni Kí Owó Ìrànwọ́ Ìjọba Àpapọ̀ Kárí -Ilé, Kárí-Oko- Báńkì Àpapọ̀ Àgbáyé

218

Ìpín péréte nínú àwọn aláìní tí ìjọba fojúsùn ni ó sẹ̀ṣẹ̀ gba owó ìrànwọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n ní osù kan tí ìjọba se àgbékalẹ̀ rẹ̀

Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ètò ọrọ̀ ajé tí Báńkì Àgbáyé fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Alex Sienaert ni ó fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ìlú Abuja, nígbà tí ó ń sàlàyé nípa ibití wọ́n ba iṣẹ́ dé fún osù kejìlá ọdún 2023

 

Gẹ́gẹ́ bí ó se sọ, Ó sàlàyé èròńgbà ìjọba láti pín owó ìrànwọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n fún osù mẹ́ta, fún àwọn tí ó kù díẹ̀ kààtó fún láwùjọ. Ó tẹ̀síwájú pé ènìyàn mílíọ̀nù kan àbọ̀ ni ó sẹ̀sẹ̀ gba owó náà nínú àfojúsùn mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gún ènìyàn tí ìrètí wà pé yóò jẹ ànfààní ètò náà

 

Ó tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn ní kò ní ohun àmúyẹ èyí tí yóò mú wọn kojú òsùwọ̀n láti jẹ ànfààní owó náà. Ó wá pàrọwà sí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti se ohun tí ó yẹ, kí wọ́n le è jẹ ànfààní ìjọba.

Comments are closed.

button