Mínísítà Fún Eré ìdárayá Ṣe ìlérí Láti Ṣe Àtìlẹ́yìn Fún Awọn Ilé iṣé Aláàdáni Lórí Ọ̀rọ̀ Eré ìdárayá
Mínísítà Fún Eré ìdárayá Ṣẹ́nitọ̀ John Owan Enoh ti ṣe ìlérí láti ṣe àtìlẹ́yìn nla fún àwọn ilé iṣé Aláàdáni nípa ọ̀rọ̀ Eré ìdárayá.

Mínísítà sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí o ṣe ìbẹ̀wọ̀ sí Olu ilé iṣé Bóòlù alafesegba ti wọn ni ni Start Football ni Ikénne ni ìpínlẹ̀ Ògùn,ni ọjọ́ àbámẹ́ta.
Ṣẹ́nitọ̀ Enoh sọ wí pé labẹ ijoba òun àwọn yóò gbìyànjú láti ṣe àwọn àtúnṣe tí o yẹ ki eré ìdárayá ba le di ohun idunnu sí àgbáyé.
Ó Gbóríyìn fún Soname àti gbogbo òṣìṣẹ́ fún rẹ bi wọn se n mú Ìdàgbàsókè bá ètò ọ̀rọ̀ Bọ́ọ̀lù alafesegba ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíría.
Ó ní ipa kekere kọ ni àwọn ilé iṣé Aláàdáni n kọ lori ọ̀rọ̀ eré ìdárayá.
Soname wa fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí mínísítà fún ìbẹ̀wọ̀, o ní mínísítà ní yóò jẹ ẹni àkókò tí yóò ṣe ìbẹ̀wọ̀ láti ìgbà tí wọn ti ṣi ilé iṣé náà.