Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti tẹ́ pẹpẹ ètò ìsúná tí ó tó tírílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n sí iwájú ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin fún ọdún 2024. Ó sàlàyé pé ìjọba yóò sé àmúsẹ ètò ìsúnná náà láti mú ìgbòòrò bá ètò ọrọ̀ ajé, tí yóò sì mú ìdẹ̀kùn bá ará ìlú, àtipé yóò yọ Orílẹ̀-èdè Naijiria kúrò nínú ìlekoko tí yíyọ ìrànwọ́ orí epo dá sílẹ̀
O ́sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń tẹ́ pẹpẹ ètò ìsúná tí ọdún 2024 síwájú Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ní ìlú Abuja
Àarẹ sọ pé ó dá òun lójú pé ilé ìgbìmọ̀ Asòfin yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ tí yóò sì mú kí iṣẹ́ síṣe lórí ètò ìsúná náà yá kán-kán. Ó fi àrídájú hàn pé ètò ìsúnà náà yóò dí lílò ní ọjọ́ kíní osù kíní ọdún 2024.
Leave a Reply