Àwọn aráàlú Morocco ṣé iwọde ní àtìlẹ́yìn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Palestine ní Casablanca, wọ́n n pé láti fòpin sí rògbòdìyàn Gaza, kí ìjọba Orílẹ̀-èdè Morocco sí fòpin sí ìbaṣepọ̀ wọ́n pẹ̀lú Israeli.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló gba ojú pópó-ọnà tí Casablanca, pẹ̀lú àsíá ilẹ̀ Palẹ́síténì lọ́wọ́, tí wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀ keffiyeh dúdú àti funfun.
Àwọn afẹhonu hàn wọnyí pé fún òpin àjọṣepọ̀ tó wà láàrín Morocco àti Israeli, èyí tí wọ́n ṣẹ̀ tún ṣé ní ọdún 2020 gégébí apakan tí ìlànà tó gbòòrò láàrin Israeli àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lárúbáwá.
Ẹhonu náà wá ní ọjọ́ kẹta tí ìdúró ogún ọlọjọ mẹ́rin láàrin Israeli àtí Hamas, lẹyìn ọsẹ méje tí ogún tí bẹ́ sílẹ̀ èyí tó tí fá ikú ẹgbẹ̀rún mẹẹdogun àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Palestine àtí ẹgbẹfa àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Israeli, ní ìbámu sí àkọọlẹ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àwọn ẹgbẹ méjèèjì.
Leave a Reply