Ààrẹ Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Godswill Akpabio tí tún pé fún ìsọkan orílẹ̀-èdè, Ó ṣé àpèjúwe onírúurú ẹ̀yà, àṣà àtí ẹsin gẹ́gẹ́ bí òun àmúse-àgbàrá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Sẹnatọ̀ Akpabio sọ̀rọ̀ yí làkókò tó ń bá àwọn ọmọ ijọ ‘Presbyterian Church of Nigeria’ sọ̀rọ̀ lásìkò ìsìn ìdúpẹ́ àti ìsìn ìlú tí aṣojú tí àgbègbè gúúsù Cross River, Sẹnatọ̀ Asuquo Ekpenyong, àti ẹbí rẹ̀ ní Calabar, Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Cross River.

Ní tó ń bá Gómìnà Ìpínlẹ̀ Cross River, Bassey Otu sọ̀rọ̀, Ààrẹ Sẹnetọ̀ rọ̀ ọ́ láti fi ‘ọkàn ìfẹ́’ ṣe àkóso àwọn aráàlú nípa ṣíṣe ìdókòwò láti ṣé ìdàgbàsókè àwọn oún àmúṣọrọ̀ tó ní alopẹ́ èyí tí yóò ṣé aráàlú láǹfààní tí yóò sì jẹ́ àjogúnbá ìjọba rẹ̀.
O gbóríyìn fún Ìgbákejì Ààrẹ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Barau Jubrin fún wiwà síbi ìdúpẹ́ náà pèlú àwọn àádọta (50) mìíràn àtí ogún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú tí Nàìjíríà, bó tún ṣé ṣàfihàn Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí Donald Duke àtí ìyàwó rẹ̀, Onari.

Ìdúpẹ́ náà ní wọ́n tí rí Alàgbà Ali Ndume, àti Mínísítà fún ọ̀rọ̀ Ọmọnìyàn àti ilé-òṣì-wọ́lẹ̀, Dókítà Betta Edu, àti àwọn mìíràn.
Leave a Reply