Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí ó wà ní ìlú Abuja ti fi ìdí ìjáwé olúborí Gómìnà Bala Mohammed ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà tí wọ́n dìbò yàn fún ìpínlẹ̀ Bauchi
Ilé Ẹjọ́ se Ìdájọ́ náà ní ọjọ́ Ẹtì, èyí tí ó fi ìdí ìyànsípò Mohammed mulẹ̀ nínú ìdìbò si ipo gomina tí ó wáyé ni ọjọ kejìdínlógún osù kẹta. Èyí se déédé pẹ̀lú ìkéde Àjọ INEC tí ó kéde Mohammed ti ẹgbẹ oselu PDP gẹgẹ bi ẹni ti o jawe olubori ninu idibi gomina ọjọ kejidinlogun osu kẹta.
Àwọn adájọ́ náà kò pàsẹ sísan owó ìtanràn, nígbà tí ìdájọ́ wáyé pe ki ikọ̀ méjéèjì gbé bùkáátà ìpẹ̀jọ́ àti ìjẹ́jọ́.
Leave a Reply