Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Charles Soludo, CFR, ti kí Sẹ́nétọ̀ Hope Uzodimma ti ìpínlẹ̀ Imo kú oríire fún ìjáwé olúborí rẹ̀ níbi ìdìbò gómìnà èyí tí ó wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkànlá osù kọkànlá ọdún 2023 ní ìpínlẹ̀ Imo
Alákòóso ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Abayọmi Fasina ni ó kéde èsì ìbò náà ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Àbámẹ́ta níbi tí ó ti fi ìdí ìjáwé olúborí Sẹ́nétọ̀ Hope Uzodimma ti ẹgbẹ́ òsèlú APC múlẹ̀, níbi tí ó ti rí ìbò òjì-lé-lẹ́ẹ̀dẹ́ẹ́gbẹ̀ta ẹgbẹ̀rún, ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́jọ (540,308), tí Samuel Anyanwu, ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP tí ó tẹ̀ lé e sì rí ìbò mọ́kànléláádọ̀rin ẹgbẹ̀run, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti mẹ́ta (71,503).
Gómìnà Soludo wá pàrọwà sí Sẹ́nétọ̀ Uzodimma láti rí ìjáwé olúborí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àseyọrí fún gbogbo ọmọ ìpínlẹ̀ Imo, Ó sì gbàdúrà fún ìkẹ́sẹjárí sá à ẹlẹ́ẹ̀kejì.
Leave a Reply