Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ Kwara Sèdárò Lẹ́yìn Ikú Gbajú-gbajà Òsèré, Samanja
Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ Kwara, Ààrin Gbìngbìn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Onímọ̀-ẹ̀rọ Yakubu Danladi-Salihu ti sàpèjúwe ikú Alhaji Usman Baba Patigi tí gbogbo ayé mọ̀ sí Samanja gẹ́gẹ́ bí òfò ńlá sí àwùjọ àwọn òsèré
Danladi-Salihu sàpèjúwe Baba Usman gẹ́gẹ́ bí akíkanjú tí ó jẹ́ ọmọ ọba Patigi. Ó wá kẹ́dùn pẹ̀lú ìdílé Samani, gbogbo ìdílé ọba Patigi àti ẹgbẹ́ òsèré lápapọ̀.
Ó gbàdúrà sí ọlọ́run Allah fún àforíjì akọni náà, àtipé kí Ọlọ́run fi ilé ìdẹ̀ra ta á lọ́re.