Ìjọba Àpapọ̀ Ti Gbáradì Láti Mú Àlékún Bá Ìpèsè Epo Rọ̀bì Lójúnà Àti Tán Ìsòro Ọ̀wọ́ngógó Epo
Mínísítà Kejì Fún Ọ̀rọ̀ Epo Rọ̀bì ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Heineken Lokpobiri ti sàlàyé pé mímú àlékún bá ìpèsè epo rọ̀bì jẹ́ ọ̀nà àbáyọ láti tán ìsòro ọ̀wọ́ngógó epo rọ̀bì ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ó tẹ̀síwájú pé ìgbésẹ̀ náà yóò jẹ́ kí epo rọ̀bì wà ní ànító àti ànísẹ́kù fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Lokpobiri sàlàyé ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta tí ó wáyé ní ìlú Abuja. Ó fi àrídájú léde pé ìjọba àpapọ̀ ti ń gbìyànjú láti máa pèsè àgbá epo rọ̀bì tí yóò tó mílíọ̀nù méjì ní ọjọ́ kan soso kí ó tó di osù kejìlá.
Leave a Reply