Take a fresh look at your lifestyle.

VP Shettima gbéra ní Abuja lọ sí China fún àpèjọ Ọ̀nà àti Ìgbànú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 182

Igbákejì ààrẹ Nàìjíríà, Kashim Shettima, yóò gbéra ní Abuja lónìí ọjọ́ Àìkú lọ sí Beijing, China, láti ṣojú ààrẹ Bla Tinubu níbi Àpèjọ Àgbékalẹ̀ Ìgbànú àti Ọ̀nà ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí ń bọ̀ lọ́nà (BRI), tí yóò wáyé láti ọjọ́ kẹrìndín-lógún sí ọjọ́ kejìdín-lógún oṣù kẹwàá, 2023.

Yoo maa darapọ mọ awọn adari lagbaaye lati orilẹ-ede ti o ju aadoje lọ ni Afirika, Yuroopu ati Latin Amẹrika nibi apejọ naa lati jiroro lori Akọle, Ìgbànú tí ó dára àti Ọ̀nà Ìfọwọ́sowọ́pọ̀: Lápapọ̀ fún Ìdàgbàsókè àti Ìlọsíwájú kannáà.”

Igbákejì ààrẹ yoo lo anfaani ti apejọ yii pese lati fa oju awọn oludokowo mọra fun idagbasoke awọn iṣẹ Akanṣe ni Naijiria.

Yoo tun ṣe ipade ilana meji pẹlu awọn Adari miiran lagbaaye lati ṣagbelarugẹ ajọṣepọ karakata ati idokowo Naijiria leyi ti o nii ṣe pẹlu Agbekalẹ idagbasoke ọrọ-aje ijọba aarẹ Tinubu.

BRI 2023 yoo sami ayẹyẹ ọdun kẹwaa Agbekalẹ Belt ati Road (BRI), ti aarẹ orilẹ-ede China, Xi Jinping, ṣagbekalẹ rẹ gẹgẹ bi eto ọgbọn fun idagbasoke Amayedẹrun lagbaaye.

Ni 2018, aarẹ igba naa, Muhammadu Buhari, lorukọ Naijiria, buwọlu Adehun ifọwọsowọpọ Igbanu ati Ọna pẹlu China.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button