Àkójọpọ̀ àwọn Oníṣẹ́ ààbò tí gbá àwọn méjì kàn àti Àlùfáà Kátólìkì kàn tí wọ́n jígbe ní ọjọ́ Ẹtì ní ìjọba ìbílẹ̀ Orumba South tí ìpínlẹ̀ Anambra, Gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà.
Alukoro ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Anambra, Ikenga Tochukwu sọ́ èyí di mímọ̀ fún àwọn aráàlú, tí ọwọ sí tẹ́ àwọn afurasi mẹ́ta kàn, ọkọ̀ mẹ́sàn pẹ̀lú ìbọn ‘Pump Action’ mẹ́ta ní wọ́n gbà lọ́wọ́ wọ́n láìsé ayọkuro aṣọ àwọn ológun Orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n jí kò, àsìá BIAFRA, ẹrọ alágbèéká loriṣiriṣi, ‘Flash Drive’, kaadi SIM èyí tí yóò ṣé ìrànlọ́wọ́ ìwádìí tó pé àti ipẹjọ.
Àwọn wọnyí ní wọ́n tí ń ṣé ìjàmbá ijinigbe loriṣiriṣi ní àgbègbè ìjọba ìbílẹ̀ náà àti ìbílẹ̀ Aguata láìpẹ́ yii.



Kọmiṣanna ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Anambra, CP Aderemi Adeoye tó pàṣẹ àti ṣètò iṣẹ́ náà gbóríyìn fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ iṣẹ́ náà àti àwọn ẹgbẹ́ Vigilante tó ṣé Ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì rí dájú pé ẹnikẹni ọ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Charles Soludo, tí yìn àwọn Òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá, ó sí ṣèlérí àtìlẹ́yìn nígbà gbogbo fún ilé-iṣé Ọlọ́pàá láti ríi dájú pé Ààbò ìpínlẹ̀ dúró ṣinṣin.
Leave a Reply