Gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe, Mínísítà ṣe ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe ilé-ìwé gíga fáfítì TETfund
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà Muhammadu Yahaya ti ìpínlẹ̀ Gombe , Mínísítà fún lílọ bíbọ̀, Sẹ́nétọ̀ Sa’idu Alkali, àti Akọ̀wé aláṣẹ ti ìgbìmọ̀ tó ń mójútó Ìnáwó àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga, TETfund, Ọ̀gbẹ́ni Sunny Echono, ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn iṣẹ́ àkànṣe lọ́lọ́kàn ò jọ̀kan ti TETfund ti ilé-ìwé gíga fáfítì ìpínlẹ̀ Gombe sonígbọ̀wọ́ rẹ̀.
Akọwe Alaṣẹ ti TETfund, Ọgbẹni Sonny Echono, sọ pe awọn iṣẹ Akanṣe mọkanla ni wọn ṣe ifilọlẹ rẹ, ninu awọn iṣẹ naa ni Agbekalẹ Ipa Pataki ti ko Lẹgbẹ, Eyi ti o yatọ,Ọdun, ati Agbekalẹ agbegbe ti o gba awọn owo naa laarin 2014 ati 2021.
Ọgbeni Echono sọ pe, “Iṣẹ Akanṣe naa ti pari ti wọn si ti ṣaṣeyege lori rẹ gẹgẹ bii adehun pẹlu ilana TETfund laarin 2021 ati 2023, ni iye owo ti o le ni Biliọnu mẹrin Naira.”

O sọ pe ile-iwe giga fafiti ipinlẹ Gombe wa lara awọn ti yoo janfaani TETfund ní 2006 titi di oni yii, ti o si ti gba iye owo to le ni Biliọnu meedogun Naira ninu agbekalẹ naa, leyi ti o jẹ ida mẹrindin-laadọrun ninu ọgọruun owo ti wọn gbe kalẹ fun ile-iwe naa.

Nigba ti o n sọrọ lasiko ṣiṣi naa, Gomina Yahaya tunbọ wa n fidi ipinnu rẹ mulẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu TETfund fun atunṣe awọn ohun Amayedẹrun ile-iwe giga naa ati ti ipinlẹ, lati pise ayika to rọrun fun ikẹkọọ ati ikọni to munadoko.

Leave a Reply