Adarí àwọn ọmọ ogun Ikọ̀ karùnlé-lọ́gbọ́n, Ajagun Mohammed Tajudeen Aminu ti sọ pé ìwà lálàáfíà àwọn ọmọ ogun àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò jẹ́ ohun pàtàkì fún àṣeyege iṣẹ́ ológun.
Ajagun Aminu sọ eyi nigba ti o dari awọn ọmọ ogun ati awọn ile-iṣẹ aabo lori yiyan ajọṣepọ ile iṣẹ ọna onibusọ mẹwaa, ní Abeokuta, olu ipinlẹ.
Eleyii wa ninu ọrọ kan ti aṣoju igbakeji adari ọmọ ogun fun eto ibaraẹniṣepọ Ikọ̀ awọn ọmọ ogun karùnlé-lọ́gbọ́n, Mohammed Goni buwọlu.

Yiyan naa gẹgẹ bi alaye jẹ fun“ lati tunbọ fidi ifọwọwẹwọ ati iṣiṣẹpọ to ti wa laarin ologun, Agbofinro Naijiria ati awọn ile-iṣẹ aabo miiran mulẹ fun aṣeyege iwa lalaafia ati igbe aye to dara lati le koju awọn ipeninija aabo ti n koju ipinlẹ naa lọlọkan ọjọkan daradara.”

Awọn ti o kopa ninu yiyan naa ni, awọn ọmọ ogun Ikọ karunle-lọgbọn, Ibudo kọkanle-lọgọrin ti Nnkan ija ogun, Ile-iwe giga ti ọmọ ogun oju omi, Agbofinro Naijiria, Ikọ alaabo fun ile orilẹ-ede, ile-iṣẹ ti n risi wiwa ati jijade lorilẹ-ede Naijiria, ile-iṣẹ to n mojuto awọn ẹlẹwọn/ọdaran, Ile-iṣẹ aabo ati idaabobo ara ilu ni Naijiria, ati ile-iṣẹ ti n ṣọ bode orilẹ-ede ati awọn Agunbanirọ ti o wa labẹ idari.

Leave a Reply