Ògbóntàrigi, Olùborí ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ nínú eré bọ́ọ̀lù Badminton, sọ pé òun yóò kópa nínú ìdíje Indonesia International Challenge ti ọdún yi, ti yóò wáyé ni Jatim International Expo Convention Centre láti ọjọ kẹtàdínlógún títí di ọjọ́ kejìlélógún.
Ìràwọ̀ ọmọ Nàìjíríà náà wọ ipele kò mọsẹ̀ kó yọ Lagos International Classics ti ọdún 2023 ni oṣù to kọjá, kò tún kópa ni ti 2023 Guatemala International látàrí ìṣòro visa.
Opeyori jẹ kó di mímọ̀ pé, kíkópa ní Paris 2024 Olympics yóò jẹ ìwásí ìmúsẹ àlá rere tí òun lá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply