Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ D’Tigers Lù Ikọ̀ Team USA Bí Ẹni Lu Aṣọ Òfì  

0 434

 

Ikọ̀ àgbà D’Tigersti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi orílẹ̀-èdè yi sílẹ̀ ni ọjọ́ Ajé lọ sí China fún ìrìn àjò eré ìgbáradì tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀ṣẹ̀ yìí’ ti yóò sì tẹnu bọpo ni ogúnjo oṣù Kẹwàá. Wọ́n lu Ikọ̀ Team USA bí ẹní lu aṣọ Òfì ni ayò màrúndínlọ́gọ̀rin sí àádọ́rin (75-70) nínú ìgbáradì wọn.

Ikọ̀ náà ti ọ̀gbẹ́ni Musa Ahmadu-Kida.
ń darí kùnà láti peregedé fún Paris 2024 Olympics níbi ìdíje tó wáyé ni ìlú Èkó ní oṣù Kejì ọdún tó kọjá.

Èyí ló jẹ́ ìgbà Kejì ti ikọ̀ Ọkùnrin Nàìjíríà yóò lù ikọ̀ akẹgbẹ́ wọn láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Wọ́n lù wọ́n ní àádọ̀rún sí ẹ̀tàdínláàdọ̀rún (90-87) ni ibi ìdíje pre-2020 Olympics ni
Mandalay Bay Arena ìlú Las Vegas ní ọdún 2021.

Ìgbákejì ààrẹ àjọ Nigeria Basketball Federation, ọ̀gbẹ́ni Babs Ogunade sọ pé àṣeyọrí náà jẹ́ èyí tó dára àti ìgbésẹ̀ tó wuyì.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button