Take a fresh look at your lifestyle.

Iyanṣẹlodi: Ẹgbẹ́ gbóríyìn fún ìjọba Nàìjíríà, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí ìpinnu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 280

Àjọ àpapọ̀ àwọn agbanisísẹ́ ní Nàìjíríà, NECA, ti gbóríyìn fún ìjọba Nàìjíríà àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí ìpinnu láti yẹ ìyanṣẹ́lódì tí kò lásìkò ní orílẹ̀-èdè.

Adari gbogbo  NECA, Ọgbẹni Smatt Oyerinde ṣe igboriyin yii ni Abuja ni ọjọ Iṣẹgun.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ti n dun huru lati rawọ le iyanṣẹlodi ti ko lọjọ ni ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, lati beere ẹtọ wọn lori ipa amukuro adinku owo epo ilẹ, leyii ti ko inira nla ba awọn mekunnu.

O wa wa tunbọ gba ijọba Naijiria nimọran lati mu ipinnu rẹ wa si imuṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ati gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede lapapọ, lati yẹ iyanṣelodi miiran.

Adari gbogbo NECA wa sọ pe “ipa iyanṣẹlodi lori abala okowo aladaani ko ṣee ro rara.”

O wa sọ pe ipele awọn okowo aladaani n foju wina, ijọba ko tun gbọdọ faaye gba ki wọn maa rẹsẹ mulẹ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button