Take a fresh look at your lifestyle.

Àlúfà ìjọ, àwọn mìíràn farapa nínú ilé ìjọsìn tí ó dàwó

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 195

Àlúfà ìjọ ile ijọsin Dunamis ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí ilé ìjọsìn ní àyíká Nọrth Bank, ní  inú ìlú Makurdi, ní ìpínlẹ̀ Benue dàwó,ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, àwọn aláṣẹ fìdí ẹ̀ múlẹ̀.

Ẹkunrẹrẹ oun ti o fa iṣẹlẹ naa ko ye ẹnikankan, ṣugbọn awọn Agbofinro fidi ẹ mulẹ ni Ọjọọru pe awọn mẹrin ti o farapa loriṣiriṣi ti n gba itọju ni ile iwosan.

Ẹni ti iṣelẹ naa ṣẹlẹ loju rẹ sọ pe, Alufaa ijọ ati awọn mẹrin ti o jẹ ọmọ ijọ naa n gbadura lọwọ lasiko ti iselẹ naa ṣẹlẹ, ni ọwọ aarọ ni ọjọ Iṣẹgun.

Awọn ibugbe ladugbo naa, pẹlu opo ina to wa layika ile ijọsin naa ni o bajẹ.

Awọn alakoso il ijọsin naa ko fesi kankan lori isẹlẹ naa lasiko ti wọn n kọ ijabọ yii ṣugbọn Kọmiṣọna fun Agbofinro ti ipinlẹ Benue, CP Bartholomew Nnamdi Onyeka sọ fun awọn oniroyin pe awọn mọ nipa iṣẹlẹ ọun.

Kọmiṣọna Agbofinro tun fidi mimu awọn afurasi mẹrin kan lori iku aarẹ ile ejọ ibilẹ tẹlẹ ri oloogbe Margaret Igbetar, mulẹ.

CP Onyeka ti o foju awọn afurasi naa han sọ fun awọn akọroyin pe iku adajọ naa wa latọwọ ẹbi rẹ pẹlu iranlọwọ awakọ rẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button