Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà pinnu láti ṣèrànlọ́wọ́ ohun èlò kòseémánìí fún ìdẹ̀rùn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 453

Ijọba Nàìjíríà ti pinnu láti pèsè ohun èlò kòseémánìí fún ìdẹ̀rùn àwọn ará ìlú, nípasẹ̀ ìfọkànsí rẹ̀ níṣíṣe àtúnṣe Ìrètí ní orílẹ̀-èdè.

Minisita fun eto iranlọwọ ati igbogunti ipọnju, Dokita Betta Edu n fi idi eleyii mulẹ lasiko ifilọlẹ eto  School-to-Kitchen ati ifilọlẹ eto N-Power ati N-Skills fun awọn ti wọn fipa ṣi nipo ní Gwada ati ibudo awọn ti wọn fipa ṣi nipo ni ijọba ibilẹ Kuta Shiroro ní  ipinlẹ Niger, Ariwa Aringbungbun Naijiria.

Dokita Edu wa fidunnu rẹ han pe awọn ohun itura naa yoo ṣeranlọwọ fun wọn, gẹgẹ bi ijọba ṣe pinnu lati pese atunṣe ti yoo tu awọn ẹbi wọn lara.

O tun wa tẹnumọ pe aarẹ Bola Ahmed Tunubu ti pinnu lati ṣe atunṣe to yanranti si wahala orilẹ-ede, nigba ti o n sọ ipa ti awọn adigunjale ko, ni eyi ti o fa ifipa ṣini nipo pada awọn ọmọ ipinlẹ Niger, ti ko niye. Eyi tun fa titi awọn ile-iwe to le ni irinwo pa jakejado agbegbe ipinlẹ naa, ti ẹgbẹrun mọkanla awọn ọmọ ile-iwe ko si le tẹsiwaju lori ekọ wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button