Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ wí pé ìpinu àwọn ní láti kọ pàpàkọ̀ òfurufú ti ko lẹ́gbẹ́ ni ilé Áfíríkà.
Mínísítà fún Pápákọ̀ òfurufú Ògbéni Festus Kayamo lo sọ èyí di mímọ̀
Níbi ìpàdé àwọn òṣìṣẹ́ Pápákọ̀ òfurufú ti ẹlẹ́ẹ̀kéje irú rẹ, to wáyé ni ìlú Abuja ní Ọ̀rọ̀ náà ti jáde.
Adarí àwọn ìdánilékọ̀ọ́ fún Pápákọ̀ òfurufú ni Orílẹ̀-èdè UK Ìyáàfin Silke Buckley sọ nibi ìdánilékọ̀ọ́ náà wí pé ìpàdé náà wà fún ìdàgbàsókè àwọn Òṣìṣẹ́ Orílẹ̀-èdè tó n ṣiṣẹ́ ni Pápákọ̀ òfurufú àti ilé adulawọ lápapò.
Ìyáàfin Buckley sọ wí pé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni gbogbo ohun to gbà láti jẹ ẹni àkọ́kọ́ nínú iṣé Pápákọ̀ òfurufú.
Leave a Reply