Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asojú sòfin, Abbas Tajudeen ti kẹ́dùn látàrí ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé káàkiri orílẹ̀-èdè yi láìpẹ́.
Nígbà tí ó ń sọ ojú abẹ nìkó látàrí ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Adamawa àti Niger, ó pé fún akitiyan ìjọba àti Olùdarí ọkọ̀ ojú omi láti máa dóòlà ẹ̀mi àti dukia àwọn ènìyàn lórí omi orílẹ̀-èdè yìí.
Abẹnugan bu ẹnu àtẹ́ lu ìrìnna ojú omi tó jẹ ọ̀nà míràn láti se irin àjò yatọ̀ sí ti orí ilẹ tàbí ti Reluwé fún àwọn ènìyàn àti ẹrù wọn tó wá di
pańpẹ́ ikú báyìí.
Abẹnugan Abbas ke pe àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti se gbogbo ohun tó yẹ láti lè máa dóòlà ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn tó bá wọ ọkọ̀ ojú omi láti má jẹ́ kí ìjàmbá wáyé mọ́ pàápàá jù àwọn tó ń wa ọkọ̀ àti àwọn ènìyàn ti wọ́n ń wà.
Ó bá ẹbí, ènìyàn àti ìjọba ìpínlẹ̀ Niger àti Adamawa ṣọ̀fọ̀, ó tún gbàdúrà fún àwọn tó kù nínú àwọn ìjàmbá náà kí Ọlọ́run tẹ́ wọn sí afẹ́fẹ́ rere.
Ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n ròyìn pé wọ́n kú látàrí ìdojúdé ọkọ ojú omi ní ibi omi pẹ̀lú àlà ilẹ̀ ti Njuwa, abà Rugange ni gúsù Yola ìjọba ìbílẹ̀ Adamawa.
Bákannáà ní ọjọ Àìkú, Ọkọ̀ ojú omi ti Ọgọ́rùn ún èniyàn wà nínú rẹ̀ ní ìjọba ibilẹ Mokwa, ìpínlẹ̀ Niger náà tún dojú dé, ó pa ènìyàn Ọgbọ̀n.
Kò tán síbẹ̀, ní ọjọ Ajé, ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní agbègbè Kwatan Mallam Adamu, abà Gurin, ìjọba ìbílẹ̀ Fufore ìpínlẹ̀ Adamawa tún wáyé tó gba emi eniyan mẹ́wàá.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply