Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àyíká, Dokita Iziaq Salako ti kì ààrẹ Bola Tinubu kú oríire bí àjọ PRESIDENTIAL Election Petition Tribuneal se kéde pé ọ yege nínú ìdájọ́ wọn.
Dókítà Salako sọ pé ilé ẹjọ́ jẹ́ kó di òtítọ́ pé ìbò tó gbé ààrẹ Tinubu wọlé fi òdodo
ìfẹ́ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yí hàn.
Ó sọ síwájú pé, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ní ìgbàgbọ nínú ìjọba ààrẹ Tinubu gẹ́gẹ́ bí bàbá Nàìjíríà tuntun.
O tún kí ààrẹ Tinubu kú oríire fún ọgọ́rùn ún ọjọ́ rẹ̀ lórí àlééfà, ó wá gbóríyìn fún akitiyan rẹ̀ láti mú orílẹ̀-èdè yi dé ilẹ̀ ìlérí àti ibi ọrọ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply