Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Gbéra Ní Ìlú Abuja Fún Ìpàdé G20

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 318

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu tí gbéra kúrò ní Abuja ní àárọ̀ Ọjọ́ Ajé látí lọ sí Àpéjọ Awọn ìgbìmọ̀ G-20 ní New Delhi, India, lórí ifiwe pé pàtàkì tí Alákóso India, Narendra Modi.

Nínú àtẹ̀jáde kàn tí olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Ààrẹ lórí ètò ìròyìn àtí ìkéde, Ajuri Ngelale, fọwọ́ sí, ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tún sọ pé àwọn ń gbá ìmọràn kàákiri látí mọ́ àwọn ànfàní àti èwù tó wà nínú dì darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ G20.

Àlàyé náà tún ṣàlàyé pé Ààrẹ tún gbèrò látí ló ànfààní ìpàdé náà látí ṣé ìjíròrò ìdókó-òwò tààrà pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ òkèèrè lórí ètò-ọ̀rọ̀ àjé Nàìjíríà fún ìpèsè iṣẹ́ àtí owó.

Ìpàdé G20 náà ní yóò wáyé ní New Delhi-India láàrín ọjọ́ kẹsán sí ikẹwàá, Oṣù Kẹsán, 2023.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button