Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna Se Ìlérí Láti Mú Ìdá Mẹ́ẹ̀dógún sílẹ̀ Nínú Owó Ìjọba Fún Ètò Ìlera.

0 262

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani tu ìlérí rẹ ṣẹ nínú ìjọba rẹ wí pé òun yóò ri daju wí pé ètò ìlera àti ilé ìwòsan ìjọba yóò di ara ọ̀tọ̀ ni ìpínlẹ̀ Kaduna.

Gómìnà Sani sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí o gbàlejò láti ààfin ,Oba Sokoto Alhaji Muhammad Sa’ad Abubakar III èyí tí Ọba Argungu sójú fun, lati ile ìwòsan ìjọba,(NPHCCDA) àjọ àgbáyé fún ìlera àti àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera lágbayé, pẹ̀lú àwọn tọrọ kan ni wọn jọ peju sí ilé iṣé ìjọba tó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

Ó ní ìdá mẹdogun ninu owó ìjọba  ti o n wọlé sàpó ìjọba ìpínlẹ̀ náà ni awọn yóò ma fi se ìrànlọ́wọ́ fún ilẹ ìwòsan ti ìjọba ni ìpínlẹ̀ Kaduna.

Nínú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ ti rẹ Ọba tí ìpínlẹ̀ Sokoto, Alhaji Muhammad Sa’ad Abubakar ṣàlàyé àwọn èròngbà ti  àwọn lọ́balọ́ba fún Gómìnà  wí pé àwọn yóò ṣe atilẹyin fún ilẹ ìwòsan ìjọba láti dènà àìsàn rọmọ lápá àti àwọn àìsàn míràn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button