Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Niger So Àtìlẹ́yìn Wọn Fún Àwọn Agbófinró Le Dain-dain

0 233

 

Gómìnà Ipinlẹ Niger ni àárin gbùngbùn Àríwá Nàìjíríà, Mohammed Bago ti sọ pé atìlẹ́yìn ìjọba òun tó le le dain-dain wà fún àwọn agbófinró ní ọnà láti gbógun ti àwọn ọ̀daràn ní ipinlẹ náà.

Gómìnà Bago sọ èyí ní ìgbà tí ó gba ọ̀gá àgbà àjọ Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), Doykita Ahmed Audi ní àlejò ni ilé ìgbàlejò ìpínlẹ̀ Niger tó wà ní Àbújá.

Gómìnà gbóríyìn fún àjọ NSCDC ni ìpínlẹ̀ náà, ó wá se ìlérí pé ìjọba òun yóò túbọ̀ pèsè àyíká tó dẹrùn fún àjọ náà láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́.

Ọ̀ga àgbà àjọ NSCDC, Dokita Ahmed Audi sọ pé òun wà ní ilé ìgbàlejò ìpínlẹ̀ Niger tó wà ní Àbújá láti wá fi ẹ̀mí ìmore hàn fún Gómìnà Bago fún atìlẹ́yìn fún àjọ wọn.

Dókítà Audi tún sọ pé, àwọn o ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbófinró yòókù láti ri wí pé
àwọn agbésùnmọ̀mí, ajínigbé, ajíẹrangbé àti àwọn ọ̀daràn Ìgbàlódé yókù tẹ ọwọ́ ọmọ wọn bọ asọ ní ìpínlè náà.

Dókítà Audi wá lo àsìkò náà láti ki Gómìnà náà fún ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé láìpẹ́ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbófinró ṣọ ẹ̀mí wọn nù, tí dúkìá sì ṣòfò pẹ̀lú ní ìpínlẹ̀ náà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button