Take a fresh look at your lifestyle.

Asọ́lé Spain, David Raya Darapọ̀ Mọ́ Ikọ̀ Arsenal Láti Brentford

0 248

Asọ́lé Spain, David Raya ti lọ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ Arsenal láti Brentford ni Mílíọ̀nù mẹ́ta Euro, Kílọ̀bù so bẹ́ẹ̀.

Raya, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n jẹ́ ògbóntarigì fún ikọ̀ Brentford, wọ́n kò gbá bọ́ọ̀lù wọ ilé rẹ̀ ní ìgbà ogún tó sọ́ ilé, ó fara hàn ní ìgbà ọgọ́jọ ó lé ọ̀kan nínú gbogbo ìdíje, ó kópa ní ìgbà méjì fún orílẹ̀-èdè Spain.

Raya jẹ́ ẹni kẹrin tí ikọ̀ Arsenal rà ní Sáà yí lẹyìn agbábọ́ọ̀lù bíi Declan Rice, Jurein Timber àti Kia Havertz.

Yóò máa jà raburabu láti gba ipò asọ́lé kínní fún ikọ̀ Arsenal’s pẹ̀lú Aaron Ramsdale.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button