Take a fresh look at your lifestyle.

Iná Tó Lágbára Ní Ìlú Maui Sọ Mẹ́tàléláàdọ̀ta Ènìyàn Di Olóògbé

0 222

 

Iná tó lágbára ni Ìlú Maui sọ Mẹ́tàléláàdọ̀ta èniyàn di olóògbé, ó di dandan kí oye àwọn ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn lọ sókè sí, ìlú ibi ìgbafe Lahaina náà fara kásá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ aburú náà, yóò tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí wọn tó lè tù ìlú náà kọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù döla, òṣìṣẹ́ kan ní Hawai sọ èyí.

Gómìnà Josh Green sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ iná burúkú to sọ ìlú Lahaina di ahoro jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àmúwá Ọlọ́run tó le koko júlọ nínú ìtàn. Ó ti sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn di aláìnílé lórí, ẹgbẹ̀rún ilé ló tẹ̀rì

Iná burúkú bí òrun àpáàdì náà bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun láti ìta ìlú tó fi ṣẹ́ wọ inú ìlú Lahaina tó jẹ́ olú ìlú Hawai tẹ́lẹ̀.

Àwọn panápaná gbìyànjú láti pa iná náà, ikọ̀ tó ń wá ènìyàn tó nù tó ń dóòlà ẹ̀mí ni wọn kò tíì ri gbogbo àwọn tó ti kú, gbogbo ìgbìyànjú ni ìjọba sì ti ń se. Lára wọn ni lílo Ajá tí wọ́n kó wá láti California àti Washington fún ìrànwọ́ àwọn ti ń wá ènìyàn kiri, àwọn òṣìṣẹ́ sọ bẹ́ẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn tó wà fún Irinajo ìgbafẹ́ ni wọ́n ti kó kúrò ní ìwọ̀ Oòrùn ìlú
Maui tó lé ní oye ènìyàn bí ìgbà ẹgbẹ̀rún ó dín.
.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button