Gómìnà ìpínlẹ̀ Cross River, Alàgbà Bassey Otu tí fí ọkọ túntún Ford Edge tọrẹ́ fún àwọn adájọ́ àgbà, lẹyìn oṣù kàn tí wọ́n ṣé àbẹwò sí ọfisi rẹ̀.
Nígbàtí o n ṣé àfihàn àwọn ọkọ náà ní Calabar, Olú-ìlú tí Ìpínlẹ̀ Cross River, Gómìnà Otu fí ẹdun ọkàn rẹ̀ hàn pé àwọn adájọ́ àgbà náà tí ṣé ìfárádà tó pọ̀, bẹ̀ẹ́ ló ṣé ìlérí ìyípadà réré ní ẹ̀ka náà.


Ó tún sọ fún wọ́n nípa àwọn èròngbà rẹ̀ látí bẹ̀rẹ àtúnṣe àti ìdàgbàsókè gbogbo àwọn kóòtù láàrín ìpínlẹ̀ Cross River.

Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà Ọ̀gbẹ́ni Elvert Ayambem pẹ̀lú Àkọwé ìjọba ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Anthony Enoh, Olórí òṣìṣẹ́ fún Gómìnà, Emmanuel Ironbar, àtí Olórí gbogbo òṣìṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Cross River, Ọ̀gbẹ́ni Agbang Akwaji wà lára àwọn tó wà níbí ayeye náà.
Leave a Reply