Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú tí ṣetán látí yán ìgbìmọ̀ kàn látí ṣé ìwádìí “ọkọ àjàgbé èpò ní Ore ní ìjọba ìbílẹ̀ Odigbo ní Ìpínlẹ̀ Ondo tó gbá ẹ̀mí ọgbọ̀n.
Ilé náà fẹ́ mọ́ ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pẹ̀lú wíwá Ojútùú sí láti má jẹ́ kí irú rẹ̀ wáyé mọ́ ní gbogbo ibí lórílẹ̀-èdè yìí kì wọ́n sì jábọ padà fún ilé láàrín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin.
Èyí ní ìgbésẹ Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú lẹyìn tí aṣojú Ileluji/Okeigbo/Odigbo Federal constituency Festus Ayodele Adefiranye, fí ìbànújẹ rẹ̀ hàn ní Ọjọ́rú.
Gẹ́gẹ́ bí Aṣojú Adefiranye ṣé sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà ló gbá ẹ̀mí tó jù ọgbọ̀n lọ́. Nínú wọ́n ní Obìnrin alaboyun, ọmọdé mẹ́ta àti o kéré jù marundinlọgbọn (25) àwọn èèyàn mìíràn ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtalelogun 23 Oṣù Keje, ọdún 2023, nígbàtí ọkọ àjàgbé èpò kàn ṣubú.
Leave a Reply