Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Rọ Ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Láti Ṣiṣe Pẹlu Ìjọba Fún Ìlọsíwájú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

0 236

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ké sí àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìṣèjọba rẹ̀ bi o ṣe n gbìyànjú láti fí ètò ẹ̀kọ́ ṣe ògúnná pàtàkì nínú ohun gbogbo.

Makinde lo sísọ lójú ọrọ yìí lásìkò tó lọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹwàá. Ètò tó waye ni gbàngàn Ile Ìgbìmọ̀ Aṣòfin tó kalẹ sí Sekiteriati Ìjọba ni agbègbè Agodi ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, níbi tó tí rán gbogbo ọmọ ilé létí ìlérí rẹ̀ tó ṣe ni sáà ìṣèjọba àkọ́kọ́ pé òun yóò fún ètò ẹ̀kọ́ ni ìdá mẹ́ẹ̀dógún sí ìdá ogún nínú ìdá ọgọrun ètò ìsúná.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Gómìnà ní: “A ti ṣèlérí fún àwọn èèyàn rere Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wí pé a ó ya ìdá mẹ́ẹ̀dógún sí ìdá ogún ètò ìsúná fún ẹka ètò ẹkọ, nígbà tí a ó gbé ìgbésẹ̀ láti dá ìdá ogún nínú ida ọgọrun ọmọ ti kò sí ní ilé ẹkọ padà sí yàrá ìkàwé”

“Àfojúsùn wa ni pé tí a bá gbé àbá eto ìsúná ka iwájú ilé gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe ni Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kẹsan, ẹ o gbàá wọlé láì fi àkókò ṣòfò.”

Nígbà tí o n sọrọ lórí ìfilọ́lẹ̀ ilé ìgbìmò aṣòfin kẹwàá, Makinde sàlàyé pé, èyí ni ìgbà àkọkọ tí mẹrinla nínú ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yóò tún padà sí ilé. Ó wá tẹnu mọ pé eléyìí ṣe àfihàn pé ìlọsíwájú ti dé bá ìṣèjọba ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ó wá kí gbogbo ọmọ ilé kú oríire, ni pàtàkì jùlọ àwọn ọmọ ilé Mẹ́tàdínlógún ti àwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ dibo yàn, nínú èyí tí Mẹrinla nínú wọn jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ti ẹnikan yòókù sì jẹ ọmọ ẹgbẹ òṣèlú APC.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button