Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Agbófinró Kuje ṣàwárí ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ àti àwọn mìíràn ní ìpínlẹ̀ Nasarawa

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 236

Àwọn Agbófinró ìpínlẹ̀ Nasarawa ti ṣàwárí ẹlẹ́wọ̀n Kuje kan tó sálọ àti àwọn mìíràn tí wọ́n furasi bí ọdaran ní ìpínlẹ̀ náà.

Olùpolongo fún Agbófinró (PPRO) ní ìpínlẹ̀ náà, DSP Ramhan Nansel, sọ eléyìí nígbà tí wọ́n ń ṣàfihàn àwọn afurasí náà,ní olú ilé-iṣẹ́ Àwọn Agbófinró ní Lafia, olú ìlú náà.

O sọ pe wọn mu ọdaran to salọ nitori pe ó fọle ti ó sì jí ẹrọ lalagbeka meji ati ẹrọ amohunmaworan kan.

Haruna Sunday, sọ pe oun kabamọ nnkan tí oun ṣe,nigba ti ó ń dahun ifọrọ wanilẹnuwo.

Bákannáà, ni wọ́n tún ṣe àfihàn àwọn ọ̀daràn mẹtadin-logun miiran fun awọn ọran loriṣiriṣi, jákèkádò ìpínlẹ̀ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button