Ààrẹ Tinubu ṣèdárò àwọn tó fara káàsá ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi ní ìpínlẹ̀ Kwara
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Bọla Tinubu banújẹ́ lórí ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi tó ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kwara, léyìí tó gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, ìjàm̀bá náà gba ẹ̀mí ènìyàn to lé lọ́gọ́rùn ún tí ó jẹ́ àlejò níbi ìgbéyàwó kan, ní abúlé Egbu, ní ìjọba ìbílẹ̀ Patigi, ní ìpínlẹ̀ náà.
O wa n rọ ijọba ipinlẹ Kwara àti awọn ile-iṣẹ ijọba apapọ ti iṣẹ wọn ba jọ mọ, lati ṣewadii nnkan to le ṣokunfa iru ijamba naa,aarẹ Tinubu wa pinnu pe ijọba oun yoo siṣẹ lori ipeninija ti o ń koju lilọ bibọ lori omi lorilẹ-ede lati pese aabo.
Leave a Reply