Agbófinró da àwọn òṣìṣẹ́ síta láti fòpin sí àṣẹ kónílé ó gbélé IPOB
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Kọmíṣọ́nà Agbófinró ti ìpínlẹ̀ Enugu , Ọ̀gbẹ́ni Ahmed Ammani, ti da àwọn òṣìṣẹ́, àwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́ àti ti ìṣiṣẹ́ ọpọlọ láti pèsè ààbò, ní ọjọ́ Ajé àti gbogbo ọjọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.
Eléyìí wá lẹ́yìn àṣẹ Gómìnà Peter Mbah, ọjọ́ kinni,oṣù Òkúdù, tí ó fagilé kónílé ó gbélé ẹgbẹ́ olómìnira àwọn ènìyàn Biafra, tí wọ́n bẹnu àtẹ́ lù ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ní gbogbo agbègbè gúsù iwọ̀ oòrùn.
Gómìnà Mbah tún wá kéde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, pé òun yóò ti àwọn ilé-ìwé, ọjà, ilé-ìtajà kéékèèkéé, ilé-ìwòsàn, àwọn oní mọ́tò, ilé-ìtajà ńlá tó bá tún tẹ̀ĺe àṣẹ kónílé ó gbélé IPOB pa ni.
Mbah ti wá yan àwọn amúni tí yóò ṣàmójútó ìtẹ̀lé àṣẹ tuntun náà láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ karùn ún,oṣù Òkúdù.
Leave a Reply