Take a fresh look at your lifestyle.

A Ní Láti Bẹrẹ Ìgbésẹ̀ Àtúnṣe Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Báyìí: Makinde Sọ Fún Àwọn Èèkàn Ẹgbẹ́

0 259

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òyó Seyi Makinde tí ké sí gbogbo àwọn èèkàn ti ọrọ Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP jẹ lógún láti gbàgbé ìkùnsínú àtẹ̀yìnwá, ki wọn ṣetán láti ṣe àtúnṣe, ki wọn sì ṣiṣẹ papọ̀ fún iṣọkan ẹgbẹ́ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí Akọwe ìròyìn fún Gómìnà, Sulaimon Olarewaju fí ọwọ́ sí tó sì fí síta fún àwọn oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló sàlàyé wí pé Gómìnà Makinde sọ ọrọ yìí di mímọ lásìkò tí ẹgbẹ òṣèlú PDP ṣe àgbékalẹ̀ ìpàdé fún àwọn tí ìlú dibo yàn ní ìlú Bauchi tìí ṣe olú ìlú Bauchi ní Ẹkùn Àríwá Ìlà Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àtẹ̀jáde náà tún jẹ kó di mímọ pé, Gómìnà tẹnu mọ fún ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà láti yàgò fún gbogbo ohun tó lè fa darudapọ nínú ẹgbẹ́ látàrí ìkùnsínú to ṣúyọ lásìkò ètò ìdìbò gbogboògbò to kọjá, ki wọn sì gbà àlàáfíà láàyè.

Makinde gẹ́gẹ́ bí ọrọ rẹ ní: “Mo fẹ sọ di mímọ wí pé a ti la làásìgbò ètò ìdìbò kọjá, tí a bá sì fẹ́ gbà tàbí a kọ láti gbà, a ní darudapọ láàrin ara wa lásìkò ìdìbò. Ṣùgbọ́n, ohun kan lo dájú, àtúnṣe ni láti bẹrẹ, ó sì gbọdọ̀ bẹrẹ nisinsinyi.”

Makinde tún fi kún ọrọ rẹ̀ pe kí gbogboo ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni afojusun, nígbà tí o gba àwọn Gómìnà níyànjú láti dúró tiiri, ki wọn sì tẹ̀ síwájú nínú ojúṣe ìmúpadàbọ̀sípò ẹgbẹ́ náà.

Gómìnà wa sọ lakotan fún gbogbo àwọn tó péjú síbi ìpàde náà pé: “Ìjọba yóò wá, yóò sì lọ, ṣugbọn orilẹ èdè wa yóò wà sibẹ. Gẹ́gẹ́ bíi ẹgbẹ́ òṣèlú alatako to lóye, a ní láti ṣe ohun gbogbo fún ire Orílẹ̀ èdè yìí. Nítorí, tí kò bá sí Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ko lè sí àwa.”

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button