Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn, Bọla Ahmed Tinubu ti lu ìlù gbọ-in gbọ-in ni a wà lẹ́yìn rẹ fún Hilda Baci, nígbà tí ó setán láti gba àmì ẹ̀yẹ àgbáyé ẹni tí ó le è dáná oúnjẹ jùlọ.
Láti gba àmì ẹ̀yẹ náà, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náà bẹ̀rẹ̀ síse oúnjẹ fún ọjọ́ mẹ́rin ní Ọjọ́bọ̀, ní àgbègbè Lekki, Ìpínlẹ̀ Èkò.
Tinubu fi àtìlẹyìn rẹ̀ léde lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi fán-án-rán kan tí ó jáde ní ọjọ́ Àìkú.
Leave a Reply