Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ọmọ Ilé-ìwé Mẹsán Pàdánù Ẹ̀mí Wọ́n Nínú Ìjàmbá Ọkọ Ojú-Omí Ni Ghana

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 290

Àwọn ọmọ ilé-ìwé mẹsán tí pàdánù ẹ̀mí wọ́n ní àgbègbè Greater Accra tí Orílẹ̀-èdè Ghana, lẹ́yìn tí ọkọ ojú-omí tó ń gbé wọ́n lọ sí ilé-ìwé rì.

Awọn ọmọde náà ní ọjọ́ orí wọ́n wà láàrín ọdún Mẹ́jọ̀ sí Mẹ́ẹ̀dógún ní wọ́n sọ pé wọ́n rìn ìrìn-àjò láti Faana sí Kelee ní àgbègbè Ga South tí àgbègbè Greater Accra ní Ọjọ́bọ̀.

Òkú àwọn mẹ́jọ tí a ríi ní a fí ránṣẹ́ sí ilé-ìwòsàn Korle Teaching Hospital lẹ́yin náà ní a rí òkú ọmọ kẹsán ní òwúrọ̀ Ọjọ́bọ̀ lẹyìn iṣẹ́ takuntakun àwọn ọdọ àgbègbè náà.

Olùdarí àgbègbè ti National Disaster Management Organisation (NADMO), Christian Afiadyo, sọ fún àwọn oníròyìn ní àgbègbè náà pé mẹ́ta nínú àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ ni ó yé ìjàmbá nla naa.

Tún kà nípa:

O sọ pé ọkàn láàrín àwọn ọmọ ilé-ìwé náà ní adari ọkọ ojú-omí náà ṣáájú ìṣẹlẹ náà, èyí tó ṣeéṣe kó wà nínú àwọn tí èwù náà fó dà botilẹjẹpe ìròyìn kó tí fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Inú ìbànújẹ ní gbogbo àwọn ará ìlú náà wà látí ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button