Ilé-iṣẹ́ Ọkọ̀ òfurufú Nàìjíríà buwọ́lu àdéhùn pẹ̀lú ìgbìmọ̀ Hajj
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ìrìnàjò mímọ́ ní Nàìjíríà lápapọ̀, NAHCON àti àwọn ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Nàìjíríà mẹ́rin ti fọwọ́sí gbígbé àwọn arìnrìn àjò mímọ́ Nàìjíríà fún ọdún 2023.
Nínú àlàyé kan tí igbákejì olùdarí ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìpolongo NAHCON, Alhaji Mousa Ubandawaki fi síta, fífọwọ́sí àdéhùn náà wáyé ní Àbújá, olú-ìlú, tí àwọn àgbà aláṣẹ NAHCON àti ti ilé-iṣẹ́ ọkọ́ òfurufú náà sì wà níjòókó níbẹ̀.
Ubandawaki sọ pé alága NAHCON, Alhaji Zikrullah Kunle Hassan gbóríyìn fún ìfẹ́ orílẹ̀-èdè tó wà lóókan àyà ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú náà lórí ìpeniníjà tí ó kojú pẹ̀lú làásìgbò Sudan.
Leave a Reply