Gómìnà ìpínlẹ̀ Ebọnyi, gúsù iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, David Umahi ti búra fún àwọn Kọmíṣọ́nà mẹ́rin tuntun bí ó ṣe ku ọjọ́ mọ́kàndín-lógún kí ìjọba mìíràn gorí oyè ní ìpínlẹ̀ náà.
Àwọn Kọmíṣọ́nà mẹ́rin náà ni Dókítà (Ìyáàfin) Obianuju Aloh – Kọmíṣọ́nà fún ètò ọkọ̀ òfurufú àti ìmọ̀ ẹ̀rọ
Ọ̀gbẹ́ni Ogbuefi Enekwachi Akpa – Kọmíṣọ́nà fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe ìjọba ìbílẹ̀ (Ọ́fíísì gómìnà)
Agbẹjọ́rò Emeka Nwode – Kọmíṣọ́nà fún iṣẹ́ òfin, (Ọ́fíísì gómìnà)
Ọ̀gbẹ́ni Nwankpuma Uchenna – Kọmíṣọ́nà fún pápá ìṣeré tuntun ti ìpínlẹ̀.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìtọ́sọ́nà, Agbẹjọ́rò Orji Uchenna sọ eléyìí di mímọ̀ nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìpádé ìgbìmọ̀ aláṣẹ tí ó wáyé ní gbọ̀ngàn EXCO, ní Abakaliki,olú-ìlú.
Leave a Reply