Ààrẹ Nàìjíríà tí wọ́n dìbò yàn forí lé Europe fún iṣẹ́ àbẹ̀wò
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Nàìjíríà tí wọ́n dìbò yàn, Bọla Ahmed Tinubu ti fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ sí Europe ní ọ̀sán Ọjọ́bọ̀, fún iṣẹ́ àbẹ̀wò.
Yóò lo ànfààní àbẹ̀wò náà láti ṣiṣẹ́ lórí ìlànà àti ètò ìgbàjọba,àti òfin lọ́lọ́kan ò jọ̀kan pẹ̀lú àwọn olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ láìsí ìkánjú tàbí ìdíwọ́.
Lásìkò àbẹ̀wò náà, Ààrẹ tí wọ́n dìbò yàn yoo jùmọ̀n sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn olùdókòwò àti àwọn alájọṣepọ̀ pàtàkì fún fífi àǹfààní ìdókòwò orílẹ̀-èdè hàn àti gbígbaradì ìṣàkóso rẹ̀ fún fífààyè gba kátàkárà nípasẹ̀ ìlànà àti ìtọ́sọ́nà.
Leave a Reply