Ààrẹ Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari yóò se ìfilọ́lẹ̀ Ilé Iṣẹ́ ìfọpo èyí tí Aliko Dangote dá sílẹ̀, ní ọjọ́ kejìlélógún osù kaàrún ọdún 2023
Olùrànlọ́wọ́ sí Ààrẹ, Bashir Ahmed sàlàyé lórí ẹ̀rọ abẹ́yẹfò rẹ̀ wípé èròńgbà ìjọba àpapọ̀ lójúnà àti mú ìrọ̀rùn bá ará ìlú lórí ọ̀rọ̀ epo rọ̀bì ti wá sí ìmúsẹ nígbà tí Ààrẹ yóò sí gbọ̀ngàn ilé ìfọpo Dangote nínú osù kaàrún.
Ilé Iṣẹ́ ìfọpo Dangote wà ní àgbègbè Lekki Free Zone, ní ìlú Èkó, tí ó sì jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Leave a Reply