Take a fresh look at your lifestyle.

Ife Àgbáyé-U-20 W/Cup: Ìkọ Flying Eagles Yóò Kojú Brazil, Italy, Dominican Republic Ní Ìpín D

0 237

 

Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Flying Eagles orilẹ̀-ède Nàìjíríà ni wọ́n ti pín sí ìpín tí ó le koko bí ojú ẹja pẹ̀lú ikọ̀: Brazil, Italy àti Dominican Republic nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 2023 tí oye ọdún wọn wà lábẹ́ ogún ọdún .

 

Ikọ̀ ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ Young Selecao ti orílẹ̀-èdè Brazil ti gba ife ẹ̀yẹ náà ni ìgbà márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

 

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ilẹ̀ olómìnira Dominican yóò kópa.

 

Ikọ̀ Flying Eagles ṣe ipò kẹ́ta ní ìdíje ife ẹ̀yẹ ti ilẹ̀ adúláwọ̀ tí ọjọ́ orí wọn kò kọjá ogún ọdún tó wáyé ní orilẹ̀-ède.Egypt ní ọdún yìí.

 

Ikọ̀ tó wà láti Iwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti se bẹbẹ rí tí wọny sì dé ipele àsekágbá ní ọdún 1989 àti ọdún 2005.

 

Ọ̀gá ọ̀ta ilẹ̀ Adúláwọ̀, Ikọ̀ ti Senegal wà ní ipín C pẹ̀lú Ikọ̀ láti Japan, Israel àti Colombia.

 

Àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ Young Scorpions ti orílẹ̀-èdè Gambia yóò kojú ikọ̀ láti France, ilẹ̀ olómìnira Korea àti Honduras ní ipín F.

 

Orílẹ̀-èdè Tunisia náà wà ní ipín E pẹ̀lú Ikọ̀ Uruguay, Iraq àti England.

 

Ìdíje náà yóò wáyé ní Orílẹ̀-èdè Argentina láàrín ogúnjọ́ oṣù Karùn ún sí ọjọ́ kọkànlá oṣù Kẹfà, ọdún yii.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button