Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje U-17 AFCON: Ikọ̀ Golden Eaglets Yóò Kọjá Lọ Sí Algeria Ní Ọjọ́ Àìkú

0 221

 

Ikọ̀ Golden Eaglets yóò kọjá lọ sí orílẹ̀-èdè Algeria ní ọjọ́ Àìkú látàrí ife ẹ̀yẹ ti ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2023 tí ọjọ́ orí wọn kò kọjá ọdún mẹ́tàdínlógún lọ.

 

Ìpín B ni wọ́n pin ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Golden Eaglets sí pẹ̀lú ikọ̀ Zambia, Morocco àti South Africa.

 

Ikọ̀ náà tí Nduka Ugbade ń tukọ̀ wọn yóò kojú orílẹ̀-èdè Morocco ní ìfagagbága wọn àkọ́kọ́ ní ọjọ́ Àìkú ti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.

 

Orílẹ̀-èdè Algeria ni yóò gba àlejò ìdíje náà tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹrin tí yóò sì parí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù karùn ún ọdún yìí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button