Ẹgbẹ́ Oníròyìn Àwọn Obìnrín Ẹ̀ka Ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Nawọ́ Ọ̀rẹ́ Sí Ilé Àkàndá Ẹ̀dá Ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Lagelu
Ẹgbẹ Oníròyìn Obìnrin ni Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NAWOJ), ẹ̀ka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣe àbẹwò sí ilé àwọn Akanda Ẹda kan ni Ìjọba Ibilẹ Lagelu ni ọna láti nawọ ọrẹ sí wọn.
Ẹgbẹ oníròyìn obìnrin ẹka ti Ìpínlè Ọ̀yọ́ labẹ ìdarí Alága rẹ, Abilekọ Jadesola Ajíbólá lo ṣe àbẹwò sí “New Dawn Orphanage” to wà ní agbègbè Ejioku ni Ìjọba Ìbílẹ̀ Lagelu, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ṣe ọkàn lára iṣẹ ìríjú ẹgbẹ náà.
Gẹgẹ bíi ọrọ rẹ, Abileko Ajibola jẹ kí o di mímọ̀ pé, ẹgbẹ́ obìnrin oníròyìn ti Ìpínlè Ọ̀yọ́ gbé ìgbésẹ yìí láti ṣe àfihàn ẹkọ ififunni tí ikú àti ajinde Jesu kristi kọ gbogbo Kristẹni, eléyìí to mú kí ẹgbẹ náà fi ẹbùn kẹkẹ (Wheel Chair) fún ọmọ tó ní ìpèníjà ìrìn àti àwọn àpò ẹfọn (Mosquito Nets) láti dáàbò bo wọn l’ọwọ àrùn ibà.
Bákan náà, ni Ajibola tún sàlàyé wí pé, ẹgbẹ́ oníròyìn obìnrin ni Ìpínlè Ọ̀yọ́ yóò tẹ síwájú nínú irufẹ ìgbésẹ̀ bayii láti ríi dájú pé wọn d’ẹrin pa ẹrẹkẹ àwọn tó ku diẹ káàtó fún.

Nígbà tí o n fi ìdùnnú rẹ hàn sí ọwọ́ ọrẹ ti ẹgbẹ́ oníròyìn obìnrin nà sí àwọn Akanda Ẹda náà, Abilekọ Funmi Ogunlade tíì ṣe Olùdásílẹ̀ àti Alakoso “New Dawn Orphanage” dupẹ gidigidi fún ìgbésẹ̀ yìí tó sì gbàdúrà kí wọn máa tẹ síwájú nínú iṣẹ́ wọn.
Ogunlade wá fi àsìkò náà ké sí Ìjọba Ìpínlè Ọ̀yọ́, ni pàtàkì jùlọ Ìjọba Ìbílẹ̀ Lagelu láti gbaruku ti wọ́n kí àwọn Akanda Ẹda náà lè ní ọjọ́ ọ̀la tó dára.
Nígbà tí o n lù Ijoba Ìbílẹ̀ Lagelu l’ọgọ ẹnu fún ọwọ iranwọ ti wọn ti n na sí ilé itọju Akanda Ẹda náà latẹyinwá, Ogunlade tún fí àsìkò náà bẹbẹ fún iranlọwọ síwájú síi.
O ní: “A n fi àsìkò yìí rọ Ìjọba wa, pàápàá ìjọba Ìbílẹ̀ Lagelu, nítorí àwọn ló sún mọ wa, ki wọn tubọ máa ràn wá lọwọ, nítorí pé tí àwọn ọmọ wọnyi ba jáde ẹkọ tàbí ẹkọ iṣẹ ọwọ, ti ìjọba sí gba wọn sí iṣẹ, ti àwọn náà ti nkan mú wálé, ọkàn wọn a balẹ, wọn kò ní máa ṣe agbe káàkiri mọ.”
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply