Ikọ̀ Liverpool gbá bóòlù sí àwọn nígbà tí ìdíje náà fẹ́rẹ̀ parí, ó jẹ́ kí ayò náà lọ sópin pẹ̀lú méjì- méjì(2-2) ní ọjọ́ Àìkú, Ikọ̀ Gunners ń fi ayò mẹ́fà ṣáájú Ikọ̀ Manchester City tó tẹ̀lé wọn báyìí nínú ìdíje bọ́ọ̀lù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ìṣẹ́jú kẹjọ tí ìdíje bẹ̀rẹ̀ ni Ikọ̀ Arsenal ti gbá ayò kan wọlé Liverpool láti ẹsẹ̀ Martinelli tí ó sì pa àwọn olólùfẹ́ Liverpool lẹ́nu mọ́.

Wọ́n tún fọba lée ní ìṣẹ́jú méjì dín lọ́gbọ̀n nígbà tí ẹlẹ́sẹ̀ ayò agbábọ́ọ̀lù Brazil ni, Gabriel Jesus, forí kan bọ́ọ̀lù wọlé. Ayò wá di méjì sí òdo (2-0). Gbogbo orí pápá sì dàrú, pé Arsenal!!!!!
Kí abala àkọ́kọ́ tó parí, Ikọ̀ Liverpool dá ọ̀kan padà láti ẹsẹ̀ Salah. Ó wá di méjì sí oókan wàyí (2-1)
Ayò náà yẹ kó jẹ́ méjì sí méjì ní ìṣẹ́jú mẹ́rìn lé láàdọ́ta nígbà ti ìkọ Liverpool ní anfààní ayò wòó kí n gba sí ọ ( Penalty) ṣùgbọ́n tí wọ́n sọ ànfààní náà nù.
Akitiyan Liverpool láti ta ọ̀mì so èso rere nígbà tí arọpò- Roberto Firmino wọlé lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́ta tó sì fi orí gbé bọọlu wọlé Arsenal, ayò wá di méjì sí méjì (2-2).
Ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ ọ̀tọ̀ ní Asöle Ikọ̀ Arsenal, Aaron Ramsdale gbà wọ́n kalẹ̀ tí kò je kí ayò wọlé rẹ̀ ní ìgbà tí ayò fẹ́ parí. Kò jẹ́ kí Salah àti Ibrahima Konate gbá bọ́ọ̀ù wọlé.

Ayò alárinrin náà parí pẹlú méjì sí méjì.
(2-2). Ọ̀mì.

Ìdíje tó ń bọ̀, Ikọ̀ Arsenal yóò kojú Ikọ̀ West Ham, Liverpoo náà yóò kojú Ikọ̀ Leeds United.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply