Take a fresh look at your lifestyle.

Anthony Joshua: Mà Fẹ̀yìntì Tí Jermaine Franklin Bá Fẹ̀yìn Mi Balẹ̀

0 338

 

Anthony Joshua sọ pé òun yóò fẹ̀yìntì nínú eré ẹ̀ṣẹ́ jíjà tí afẹ̀sẹ́kù bí òjò ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Jermaine Franklin bá fi ẹ̀yìn òun gbo ilẹ̀.

Ìdíje ìjàkadì ẹ̀ṣẹ́ wọn yóò wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ̀ta, ọjọ kínní oṣù Kẹrin ọdún yí ní O2 Arena ní Greenwich, London.

Joshua tó ti gbadé ìdíje náà léèméjì yẹ kí ó bá ọ̀gbẹ́ni Tyson Fury já tẹ́lẹ̀ ni kò leè wáyé mọ́ látàrí pé kò sí onìgbọ̀wọ́. Yóò lo anfààní ọjọ́ Àbámẹ̀ta láti dá ògo ara rẹ̀ padà lẹ́yìn tó ti pàdánù sọ́wọ́ ògbẹ́ni Oleksandr Usyk ní oṣù kẹjọ ọdún tó kọjá

“Mà fẹ̀yìntì tí n bá pàdánù ìjà yí.
N kò ṣetán láti bá ẹ̀yin olólùfẹ́ mi jà, tí ẹ̀yin tèmi bá fẹ́ kí n fẹ̀yìntì, mà fẹ̀yìntì, tí ẹ kò bá fẹ́ kí n jà, èmi náà kò ní jà”.

“Kí se ti owó, sùgbón ti ìdíje tí ó wà nínú yín ni ó se pàtàkì, “ó sọ bẹ́ẹ̀.

Joshua sọ pé kí Franklin náà ri ìjà ọjọ́ Àbámẹ̀ta bí oore ọ̀fẹ́ láti pàdé òun. Ó fi kún pé òun o gbádùn pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn kí òun tó fẹ̀yìntì bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àwọn ìdojúkọ lẹ́nu iṣẹ́ òun.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button