Take a fresh look at your lifestyle.

Èsì Ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ogun Kò Jẹ́ Àtẹ́wọ́gbà- Ẹgbẹ́ Òsèlú PDP

0 243

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ti fi àáké kọ́rí tí ó sì tako  ìkéde tí àjọ INEC se lẹ́yìn ìdìbò tí ó wáyé ní ọjọ́ kejìdílógún osù kẹta ní ìpínlẹ̀ náà. Àjọ INEC kéde Ọ̀gbẹ́ni Dapọ Abiọdun ti ẹgbẹ́ òsèlú APC gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tí wọ́n dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ náà sùgbọ́n ẹgbẹ́ òsèlú PDP kò fara má ìkéde náà.

 

Akọ̀wé ìpolongo ẹgbẹ́ náà Ọ̀gbẹ́ni Debo Ologunagba ni ó fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ìlú Abuja, nígbà tí ó ń sàlàyé ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ́ náà yóò gbé fún àwọn oníròyìn.

 

Ó sàlàyé pé ìkéde tí àjọ INEC se ní ọjọ́ Àbámẹ́ta tako àlàkalẹ̀ òfin àjọ náà ti ọdún 2022, àtipé èsì ìbò náà kún fún mọ̀kàrúrù. Ó wá pè fún àtúndì ìbò ní àwọn àyè àì-ṣe-déédé náà ti wáyé.

 

Ologunagba wá lo àsìkò náà láti gbósùbà fún ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ èyí tí ó dá Ọ̀gbẹ́ni Ademọla Adeleke láre, àtipé ẹgbẹ́ òsèlú PDP ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ètò ìdájọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button