Bí Orílẹ̀-Èdè àgbáyé se é se ayẹye àyájọ́ àwọn Adájọ́-bìnrin, ẹgbẹ́ àwọn Adájọ́-bìnrin Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lo ànfaàní náà láti sàlékún ìfarajì wọn fún ìdàgbàsókè àti ìkópa nínú ètò ìdájọ́ fún àwọn obìnrin.
Alákòsóo àgbáyé fún àjọ náà, Ẹni-ọ̀wọ̀ Adájọ́ Roli Harriman ni ó sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ àyájọ́ àwọn Adájọ́-bìnrin ti ọdún 2023.
Roli sàlàyé pé, ìsàfirinlẹ̀ ìkópa àwọn obìnrin nínú ètò ìdarí ìlú pẹ̀lú ojúgbà wọn lọ́kùnrin se pàtàkì fún ìsàkóso tí ó péye àti ìdàgbàsókè, àlàáfíà àti ìfìdímúlẹ̀ ìjọba tiwa-n-tiwa.
Ó wá sàfirinlẹ̀ ìfarajì àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà fún ìtẹ̀síwájú ìkópa àwọn obìnrin nínú ètò ìdájọ́ nì gbogbo ẹka.
Leave a Reply